Àkópọ̀ Òjíṣẹ́ Èdè Windows 7
Àkópọ̀ Òjíṣẹ́ Èdè Windows 7 (LIP) máa pèsè òjíṣẹ́ aṣàmúlò tí a tí sọ àwọn àgbègbpe tí à ǹlò júlọ nínú Windows 7 di ìbílẹ̀.
Pàtàkì! Yíyan èdè kan nísàlẹ̀ yìí yóò ṣàyípadà gbogbo àkóónú ojú-ìwé náà sí èdè yẹn.
Ẹ̀yà:
1.0
Ọjọ́ Àtẹ̀jáde:
28/1/2011
Orúkọ Fáìlì:
LIP_yo-NG-32bit.mlc
LIP_yo-NG-64bit.mlc
Ìwọ̀n títóbi Fáìlì:
2.6 MB
4.1 MB
Àkópọ̀ Òjíṣẹ́ Èdè Windows (LIP) máa pèsè ẹ̀yà Windows tí a máa ńlò jùlọ tí a ti túmọ̀. Lẹ́yìn tí a bá ti ṣe ìfiṣípò LIP, àyòkà inú onímọ̀, àwọn àpòtí ìjíròrò, àwọn mẹ́nù, àti àwọn àkọlé Ìrànlọ́wọ́ àti Àtìlẹ̀yìn máa farahàn ní èdè LIP. Àyọkà tí a kò bá túmọ̀ máa wà ní ìpilẹ̀ èdè Windows 7. Fún àpẹẹrẹ, tí o bá ra ẹ̀yà Windows 7 Spanish tí o ṣe ìfiṣípò Catalan LIP, àwọn àyọkà kan máa sì wà ní Spanish. O le ṣe ìfiṣípò jú Windows LIP kan lórí ìpìlẹ̀ èdè kansoso. O le ṣe ìfiṣípò àwọn LIP lórí gbogbo ẹ̀yà Windows 7.Àwọn Ìlànà-iṣẹ́ Ẹ̀rọ tó ní Àtìlẹ́yìn
Windows 7
• Windows 7 Microsoft
• Ìfiṣípò ìpìlẹ̀ èdè Windows 7 tí a bèèrè fún: Gẹ̀ẹ́sì
• 4.63 Mb ààyè tó sófo fún àgbàsílẹ̀
• 15 Mb ààyè tó sófo fún àgbékalẹ̀
- ÌKÌLỌ̀: Tí o bá ní Ìpàrokò BitLocker nípò ìmúṣiṣẹ́, jọ̀wọ́ dáwọ́ rẹ̀ dúró kí o tó máa ṣe ìfiṣípò LIP. Ṣí Control Panel, yan System and Security, lẹ́yìn èyí BitLocker Drive Encryption. Tẹ Suspend Protection.
Nítorípé àgbàsílẹ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ó wà fún àwọn ẹ̀yà LIP Windows 7 oníbíìtì 32 àti oníbíìti 64, kí o tó bẹ̀rẹ̀ àgbàsílẹ̀, o níláti mọ irú ẹ̀yà Windows 7 tí o ṣe ìfiṣípò rẹ̀: Èyí ni bí o ṣe máa mọ irú ẹ̀yà Windows 7 tí o ṣe ìfiṣípò rẹ̀:
Tẹ bọ́tìnnì Start lẹ́yìn èyí kí o ṣe ìtẹ-ọ̀tún lórí kọ̀ǹpútà kí o wá yan Properties. Èléyìí yóò gbé àwọn ìwífún tó ṣe kókó nípa kọ̀ǹpútà rẹ jáde.
Wo abala Ẹ̀rọ fún irú Ẹ̀rọ. Eléyìí yóò sọ bí Ìlànà-ètò ìmú ṣiṣẹ́ Windows 7 bá jẹ́ oníbíìtì 32 tàbí oníbíìtì 64.
Láti ṣe ìfisípò ẹ̀yà 32-biìtì, o le ṣe ọ̀kan nínú ìwọ̀nyìí:
- Tẹ bọ́tìnnì Download, lẹ́hìn náà tẹ Open láti ṣe ìfisípò LIP náà
- Tẹ bọ́tìnnì Download
- Tẹ Saveláti ṣẹ̀dá fáìlì náà sí orí kọ̀ǹpútà rẹ,
- Ṣàwárí ibi tí fàìlì tí a ti ṣe àgbàsílẹ̀ rẹ̀ wà kí ó tẹ̀ẹ́ lẹ́ẹ̀mejì láti ṣe ìfisípò LIP náà
tàbí
Láti ṣe ìfisípò ẹ̀yà 64-biìtì, O gbọ́dọ̀ ṣe ìfisípò ẹ̀yàn kejì tí a ṣàlàyé lókè yìí.